Enquiries, Requests: +2348073528899, 09168692180 || sales@topreliabletech.com
Time:
Below is the preview of our well-compiled, perfectly edited, nicely shaped Christ Apostolic Church Hymn's Softcopy (Yoruba Version). It contains only the first four (4) hymns, which serve as the sample copy.
All hymns have been properly formatted to display on Computer, Phone, Tablet, Projector etc. To download the full version of Christ Apostolic Church Hymns (Yoruba Version), please click here.
1. C.M
Ago Re wonni ti li ewa to, Oluwa awon omo Ogun. OD. 84:1
1 fp
Olus’agutan eni Re
Fi ara Re han wa,
‘Wo fun wa n’ile adura
M’okan wa gbadura
2. mf
Fi ami ife Re han wa
So ireti wa ji
Se’ri’bukun Re s’ori wa
K’awa le ma yin O
3 mf
K’ife ati alafia
K’o ma gbe ile yi!
F’irora f’okan iponju
M’okan ailera le
4 mf
F’eti igbo, aya ‘gbase,
Oju ‘riran fun wa;
Tan imole Re lat’oke
K’a dagba l’or’ofe
5 mf
K’a fi gbagbo gbo oro Re
K’a f’igbagbo bebe
Ati niwaju Oluwa
K’a se aroye wa.
Amin
2. 8.7.8.7
Oluwa fi igbala Re be mi wo OD 106:4
1 f
Ife orun lail’egbe,
Ayo orun sokale,
Fi okan wa se ‘bugbe Re,
Se asetan anu Re.
2
Jesu Iwo ni alanu
Iwo l’onibu ife
crFi igbala Re be wa wo
M’okan eru wa duro
3 mf
Wa, Olodumare, gba wa
Fun wa l’ore-ofe Re.
L’ojiji ni k’o pada wa,
Ma si fi wa sile mo;
4 f
Iwo l’a o ma yin titi,
Bi won ti’nse ni orun
Iyin wa ki yoo lopin
A o s’ogo n’nu ‘fe Re.
5 cr
S’asepe awa eda Re
Je k’awa lailabawon
K’a ri titobi ‘gbala Re
Li aritan ninu Re.
6 f
Mu wa lat’ogo de ogo,
Titi di ibugbe wa;
Toa fi ade wa juba Re
N’iyanu, ife, iyin.
Amin.
3. L.M
Emi tikara mi yio si ji ni kutukutu. OD 108:2
1 f
Ji Okan mi, ba orun ji,
Mura si ise ojo Re.
Mase ilora, ji kutu.
K’o san ‘gbese ebo oro
2
Ro gbogb’ojo t’o fi sofo
Bere si rere ‘se loni
Kiyesi ‘rin re l’aye yi,
Ko si mura d’ojo nla ni.
3 mf
K’oro re gbogbo j’otito,
K’okan re mo b’osan gangan
Mo p’Olorun nso ona re
O mo ero ikoko re.
4 f
Nipa ‘mole ti nt’roun wa
Tan ‘mole na f’elomiran
Jeki ogo Olorun ‘han
Ninu ife at’orun yin
5 f
Ji, gbonranu ‘wo okan mi,
Yan ipo re l’arin angeli’,
Awon ti won nkorin iyin
Ni gbogbo igba s’Oba wa.
6 f
Mo ji, mo ji, ogun orun,
Ki isin yin s’okan mi ji,
Ki nle lo ojo aye mi,
Fun Olorun mi bi ti yin.
AMIN
4. L.M
Ma rin niwaji mi, ki iwo ki o si pe.
Gen. 17:1
1 mf
Oluwa mi, mo njade lo,
Lati se ise oojo mi;
Iwo nikan l’emi o mo
Loro, lero, ati n’ise
2
Ise t’o yan mi l’anu Re,
Jeki nle se tayo tayo,
Ki nr’oju Re n’nu ise mi,
K’emi si le fi ‘fe Re han
3
Dabobo mi lowo danwo,
K’opa okan mi mo kuro
Lowo aniyan aye yi
Ati gbogbo ifekufe.
4 cr
Iwo t’oju Re r’okan mi,
Ma wa l’ow’otun mi titi,
Ki nma sise lo l’ase Re,
Ki nfise mi gbogbo fun O.
5 mf
Je ki nreru Re t’o fuye,
Ki nma sora nigba gbogbo
Ki nma f’oju si nkan t’orun
Ki nsi mura d’ojo’ogo.
6 f
Ohunkohun t’O fi fun mi,
Je ki nle lo fun ogo Re,
Ki n f’ayo sure ije mi,
Ki nba O rin titi d’orun
AMIN
To download the complete version of Christ Apostolic Church Hymn (Yoruba Version), click here