Enquiries, Requests: +2348073528899, 09168692180 || sales@topreliabletech.com
Time:
Below is the preview of our well-compiled, perfectly edited, nicely shaped Gospel Faith Mission International Hymn's Softcopy (Yoruba Version). It contains only the first four (4) hymns, which serve as the sample copy.
All hymns have been properly formatted to display on Computer, Phone, Tablet, Projector etc. To download the full version of GOFAMINT Hymns (English Version), please click here.
Orin 1
1. Maa wi, 'tori 'ranṣẹ Rẹ n gbọ,
Mo n duro de ọrọ Rẹ,
Mo fẹ gb' ohun iwosan Rẹ,
Jẹ k' emi gbọ Oluwa;
Mo tẹ 'ti silẹ Oluwa,
S' ohun t' O fẹ wi fun mi.
2. Maa wi, pe mi, Oluwa mi,
Jẹ ki n le mọ ohun Rẹ,
Maa wi, ki n yara tẹle Ọ,
Ki n sunmọ Ọ girigiri,
Nibiti O n tọ agbo Rẹ,
L' abẹ ibi itura.
3. Maa wi, yala l' ohun jẹjẹ,
Ma jẹ k' emi lọ l' aigbọ,
Maa wi, Oluwa, Iwọ mọ,
Gbogbo eero ọkan mi,
Iwọ mọ ohun ti mo n fẹ,
Sọ mi di ẹni 'bukun.
4. Maa wi, jẹ ki emi mura,
Bi mo ba ti gb' ohun Rẹ,
Pẹlu 'gbọran ati ayọ;
Ni ki n fi tẹ l' Ọrọ Rẹ,
Mo tẹ 'ti silẹ Oluwa,
Maa wi, Oluwa maa wi.
Amin.
Orin 2
1. Mo fi gbogbo ọkan mi tan,
Ẹnit' O le gb' ẹmi mi la,
Abo n la ti ki 'yẹ laelae;
Ọrọ Rẹ daju.
EGBE:
"Em' ni Alfa, at' Omega,
Ipilẹṣẹ ati opin;
Ti O wa, t' O ti wa,
Ti O si n bọ wa,
Em' ni Alfa, at' Omega,
Ipilẹṣẹ ati opin,
Olodumare, Olodumare,"
L' Oluwa wi.
2. Ọkan mi n sọ pẹlu ayọ,
Ti ẹni ti n gbe inu mi,
If' ẹni ti n tẹ l' ọrọ Rẹ,
Lati mu duro.
3. Jehofa Ọlọrun gba mi,
Lọwọ 'yemeji at' ẹru,
Fi 'gbagbọ gbigbona fun mi,
K' ọkan mi duro.
Amin.
Orin 3
1. Oluwa t' o mu Israẹl' la okun ja,
Ti O si gba wọn kuro ni oko ẹru,
Ti O rọ 'jo ounjẹ silẹ lati ọrun,
Oun ni mo n gbadura si.
EGBE:
Ọkan naa loni, Ọkan naa loni,
(Bakan naa si ni Ọlọrun ti mo n gbadura si)
B' akoko t' O sin Israẹl' la okun
Ọmọ Rẹ ni un o jẹ 'tori ọrọ Rẹ sọ
Pe ọkan naa ni Ọlọrun Iyanu loni.
2. Ọlọrun t' O gba Daniẹl' lọwọ Kiniun,
T' O si yọ awọn mẹta n'nu ina 'leru,
Ẹniti awọn Irawọ n gba Tirẹ gbọ,
Oun ni mo n gbadura si.
3. Ọlọrun t' O fọrọ Rẹ d' afẹfẹ duro,
T' o si n sọ 'banujẹ oni d' ayọ l' ọla,
Ẹniti o yi okuta 'boji kuro,
Oun ni mo n gbadura si.
4. Ọlọrun t' O wọ itanna igbẹ l' aṣọ,
Ẹniti O si mu omi ṣan l' aginju,
Ti O wẹ ẹlẹṣẹ mọ ninu eeri rẹ,
Oun ni mo n gbadura si.
Amin.
Orin 4
1. Isun kan wa t' o kun f' ẹjẹ,
T' o ti 'ha Jesu yọ:
Ẹlẹṣẹ m' okun ninu Rẹ,
O bọ ninu ẹbi.
EGBE:
A ṣa l' ọgbẹ 'tori 'rekọja,
A si pa lara 'tori ẹṣẹ wa,
Ina alaafia wa n bẹ l' ara Rẹ,
Ina Rẹ l' o n wo wa san:
A ṣa l' ọgbẹ 'tori rekọja,
A ṣa l' ọgbẹ 'tori rekọja,
Ina Rẹ l' o n wo wa san,
Ina Rẹ n wo wa san.
2. Ole ni, lor' agbelebu
Yọ lati ri 'sun naa,
Bi mo kun f'ẹṣẹ bi tirẹ,
Mo le wẹ n'n' ẹjẹ naa.
3. Gba mo fi 'gbagbọ r'isun naa,
Ti n ṣan fun ẹjẹ Rẹ,
Irapada d' orin fun mi,
Ti un o ma kọ titi.
4. Agbara t' o wa n'n' ẹjẹ yii,
Yoo wa titi laelae,
Tit' awọn ẹni 'rapada,
Y'o bọ sinu ogo.
Amin.
To download the complete version of GOFAMINT Hymn (Yoruba Version), click here